Saamu 124
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
“Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,”
kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,
nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,
nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,
nígbà náà ni omi
wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,
nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.
 
Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
okùn já àwa sì yọ.
Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
tí ó dá ọ̀run òun ayé.