Saamu 125
Orin fún ìgòkè.
Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.
Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
 
Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.
 
Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
 
Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.